Gbajugbaja oṣere tiata, Dele Odule, ni ẹnu ti bẹrẹ si ni ma kun bayii lẹyin ti to sọ pe ko si nnkan to buru ninu pe ki oṣere ọkunrin beere ibalopọ lọwọ osere obinrin, ko to fun ni ipa kan lati ninu ere sinima.
Odule ni niwọngba ti ọkunrin naa ko ba ti fi tipatipa mu obinrin ọhun fun ibalopọ, ko si aburu ninu rẹ.
O sọ eyi lasiko to n sọrọ lori eto kan lori ayelujara, Oyinmomo TV, nibi to ti sọrọ nipa iha ti o kọ si bi agbo ere sinima ṣe ri lọwọ yii.
"N ko sọ pe ki oṣere ọkunrin ma beere ibalopọ lọwọ obinrin ti oun naa jẹ oṣere, ko to fun ni ipa kan lati ko ninu ere sinima.
Amọ ti iru ẹ ba waye, o tu mọ si pe obinrin ọhun naa nifẹ lati ṣe bẹẹ ni," Dele Odule lo sọ bẹẹ.
"Ko si nnkan to buru pe wọn kọ ẹnu ifẹ si ara wọn ṣugbọn adehun gbọdọ wa laarin wọn nitori obinrin ni anfani lati gba tabi sọ pe oun ko gba"
Agba oṣere ọhun to ti wa fun igba pipẹ, ti oju rẹ si ti ri ọpọ lagbo ere sinima ni aye ti a wa bayii jẹ ibudo kan ti ọkunrin ati obinrin ti ma ba ara wọn sọrọ.
O ni o si ṣeeṣe ki ibalopo waye ṣugbọn o jẹ ko di mimọ ko si nnkan to buru nibẹ ni iwọngba ti obinrin naa ba gba lati ṣe e.
"Ni aye ti a wa yii nibi ọkunrin ati obinrin wa, ko si nnkan to buru pe wọn kọ ẹnu ifẹ si ara wọn ṣugbọn adehun gbọdọ wa laarin wọn nitori obinrin ni anfani lati gba tabi sọ pe oun ko gba," o ṣalaye.
Odule tẹsiwaju pe igbesẹ yii le di nnkan miiran to ba jẹ pe tipatipa wa ninu ibalopọ ọhun, to si ni ijiya wa fun ẹnikẹni labẹ ofin to ba ṣe si eyi.
Ọrọ yii ni ọpọ awọn eeyan tib u ẹnu atẹlu, ti wọn si n tọka si pe agbo ere sinima ti n sọ iwa bi beere ibalopọ saaju ko to kopa ninu sinima gẹgẹ bii ohun to bojumu lawujọ.
Bakan naa ni awọn mii kan saara si agba oṣere naa lori ọrọ to ṣo pe agbalagba meji ni obinrin ati ọkunrin ti iru rẹ ba ṣẹlẹ si.
Ta ni Dele Odule?
Dele Odule jẹ oṣere tiata ti wọn bi Ọjọ Kẹtalelogun oṣu kọkanla ọdun 1959.
Ilu Ile Ife nipinlẹ Osun ni wọn ti bi agba oṣere yii ṣugbọn o dagba ni ilu Oru Ijebu ni ijọba ibilẹ apa ariwa ijebu nipinlẹ Ogun.
Nibẹ lo ti kawe ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama, ko to morile fasiti Ibadan nibi to ka nipa imọ siṣe ere tiata.
Yato si pe o jẹ oṣere, Dele Odule jẹ adari ere, olootu sinima ati onkọtan.
Ọpọ ami ẹyẹ lo ti gba nidi pe o jẹ osere tiata.
Comments