"Bí Tinubu kò bá wá nǹkan ṣe lórí ètò ààbò àti ọrọ̀ ajé tó mẹ́hẹ, kò sí àṣeyọ̀rí kankan tó ṣe"

 

Ọjọ Kọkandinlọgbọn osu Karun ọdun 2023 ni wn bura fun aarẹ Bola Tinubu gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria.


Abẹ asia ẹgbẹ oselu APC si ni aarẹ Tinubu ba wọle sipo aarẹ.


Ọpọlọpọ ileri si ni Tinubu ati ẹgbẹ oselu rẹ se fun awọn ọmọ Naijiria pe awọn yoo se tawọn ba gba ijọba.


Loni yii too pe ọdun meji ti aarẹ Bola Tinubu gori aleefa bii aarẹ Naijiria, awọn ileri ipolongo ibo rẹ wo lo ti se amusẹ rẹ ati awọn agbọn to ti kuna?


BBC Yoruba kan si onwoye awujọ kan, Ọjọgbọn Gbade Ojo, to jẹ Ọjọgbọn agba ni Fasiti Ilorin ati onimọ nipa ọrọ oselu lati se agbeyẹwo isejọba Tinubu lati ọdun meji to ti gori aleefa.


Eto Aabo:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori agbeyẹwo ijba Tinubu ni ẹka eto aabo, Ọjọgbọn Gbade Ojo ni eto aabo Naijiria tun mẹhẹ tori ko tii si iyatọ gboogi ni ẹka naa.


O ni si ipa ijọba ko ka awọn agbebọn, agbesunmọmi, awọn ajinigbe atawọn eeyan miran to n huwa ọdaran tabi dunkooko mọ alaafia orilẹede yii.


"Inu fu, aya fu ni awọn ọmọ Naijiria n rin, awọn araalu ko le rin pẹlu irọrun mọ, ka to wa sọ irin alẹ.


Ojoojumọ ni gbọnmọ-gbọmọ awọn agbesunmọmi lapa oke ọya, bẹẹ ni ipa ijọba ko tii ka awọn ajinigbe-gbowo nisalẹ ọya pẹlu.


Ti a ko ba ni fi epo bọyọ, ipa ijọba ko ti ka eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.


Eto Oselu:

Ni agbọn oselu, Ọjọgbọn Gbade Ojo ni ipa Bola Tinubu ka ẹgbẹ oselu rẹ to wa ni ijọba, bi o tilẹ jẹ pe rogbodiyan n waye ninu awọn ẹgbẹ oselu yoku.


"Gbogbo eeyan gbori duro ninu ẹgbẹ APC, ti wọn si n tẹriba fun olori wọn, boya tori pe alaga ẹgbẹ APC, Ganduje fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba Tinubu ni.


Mo ri pe sise akoso Tinubu ran lọwọ lati mojuto ẹgbẹ oselu APC, ti ko si tii ya pẹrẹpẹrẹ bii tawọn ẹgbẹ oselu alatako yoku.


Gbogbo awọn ẹgbẹ alatako yoku ni wn n ni iporogan, ti ẹnu wn ko si ka ara wọn"


Ọrọ aje:

Nigba to n se agbeyẹwo ijọba Tinubu ni ẹka eto ọrọ aje, Gbade Ojo ni awọn ọmọ Naijiria ko tii ri iyatọ kan dabi alara ni ẹka eto ọrọ aje.


"Bi o tilẹ jẹ pe ijọba n kede awọn aseyọri rẹ ni ẹka eto ọrọ aje, to si ni oun n san awọn gbese ti Naijiria jẹ sọrun.


Amọ bi ijọba Tinubu se n san gbese, naa lo tun n ya owo gbese tuntun, tori naa, a ko le e ri gbese sisan bii aseyọri tori se ni gbese Naijiria tun n pọ si.


Ti araalu yoo ba ri iyatọ nipa ọrọ aje, wọn yoo beere pe elo ni apo simẹnti, ẹwa ati apo irẹsi ki Tinubu to gba ijọba, elo si ni iye owo awọn eroja naa lonii?


Koda, owo iranwọ ti Tinubu yọ lori owo epo bẹntrolu, ti da wahala gidi silẹ ni ẹka eto ọrọ aje, eyi ti ko le jẹ ki awọn araalu riran ri awọn aseyọri miran ti ijọba Tinubu se."


Kókó ọ̀rọ̀ mẹ́tàdínlógún tí Bola Tinubu sọ ní àyájọ́ ọdún kejì rẹ̀:


Gbogbo awọn igbesẹ ti ijọba apapọ n gbe lori eto ọrọ aje Naijiria ti n so eso rere


Labẹ eto Renewed Hope Agenda wa, a ṣelẹri lati mu atunṣe ba eto ọrọ aje, eto abo, fifi opin si iwa ajẹbanu, ki a si mu awọn eeyan kuro ninu iṣẹ


A mọ pe nkan ko rọrun fun awọn eeyan ati pe ọwọngogo gori ọpọ nnkan, sibẹsibẹ itẹsiwaju n ba orilẹede wa


Ọwọngogo to wa lode ti n dinku, fun apẹrẹ, owo apo irẹsi atawọn ounjẹ mii ti n pada walẹ


A ti n ṣe aṣeyọri ni ẹka epo rọbi wa ni ida 400%, eto ọrọ aje ko fi si ọtun tabi osi mọ, a ti n ni idagbasoke


Lati ibẹrẹ ọdun 2025, iye owo ti ijọba wa n pa wọle ti pọ ju iye owo ti a n na lọ


Ninu oṣu kẹrin akọkọ ọdun yii iye owo ti a pa wọle le ni tiriliọnu mẹfa naira


Kaka ki NNPC maa san owo iranwọ ori epo bẹntiro, niṣe ni oun funra rẹ n pa owo wọle fun ijọba


Ko si ọwọngogo epo bẹntiro mọ, bẹẹ ni awọn ileeṣẹ ifọpo abẹle n gberu si


Iye gbese ti ijọba wa jẹ ti dinku, bẹẹni iye owo ti a ni si ipamọ ti pọ ju ti tẹlẹ lọ


A ti san gbese ti a jẹ ajọ IMF


Biliọnu mẹrin dọla ni owo ti a ni si ipamọ lọdun 2023, ni bayii o ti le ni biliọnu mẹtalelogun dọla


Aṣeyọri mii ti a tun ṣe ni atunṣe ofin owo ori, atunṣe naa ti n so eso rere bayii


Ọpọ aṣeyọri ni a ti ṣe nipa idagbasoke awọn ọdọ


Kaakiri Naijiria, o le ni ẹgbẹrun kan ile iwosan alabọde ti a n ṣe atunṣe si, bẹẹ ni a n ra isinṣẹ si ile iwosan alabode to le ni ẹgbẹrun marun un


Bo tilẹ jẹ ọpọ idojukọ ni a ni lẹka eto abo, a n ṣe ọpọ aṣeyọri


Ni ti ohun amayedẹrun, ọpọlọpọ oju ọna ni a n ṣe kaakiri Naijiria, bi a ṣe ṣe ọna tuntun, a tun n ṣatunsẹ awọn ọna to ti bajẹ