Oyinkan Abayomi: Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni tó dá ẹgbẹ́ òṣèlú obìnrin àkọ́kọ́ sílẹ̀, tó tún jà fún ètò ẹ̀kọ́, ìṣèlú àti òmìnira obìnrin
Lati igba laelae ni awọn akọni obìnrin ti wa, awọn akinkanju obinrin bii ọkùnrin.
Ọkan lara awọn manigbagbe akọni obìnrin naa ni Oyinkansola Ajasa aya Abayomi, ti ọpọ eeyan mọ si Lady Oyinkan Abayomi.
Gẹgẹ ba ṣe ka a loju opo itakun agbaye Wikipedia atawọn oju opo miran, iṣẹ takuntakun ni Oyinkan Abayomi ṣe lati ro awọn obinrin lagbara, to si jijagbara fun ominira wọn pẹlu.
Itan sọ fun wa pe idile ọla ati ọmọwe ni Oyinkan ti wa, oun naa kawe, o si tun gbajumọ lobinrin amọ ko jẹ ki ipilẹ ọla to ni ko si oun lórí, lati maṣe naani obinrin ẹgbẹ rẹ.
Bi igbe aye Oyinkansola Ajasa Abayomi si ṣe lọ ree, eyi to yẹ kawọn obinrin iwoyi fi kọgbon ati awokọse rere.
Ibẹrẹ igbe aye Oyinkan Abayomi
Ọjọ Kẹfa, osu Kẹta ọdun 1897 ni wọn bi Oyinkansola de si idile Ọlọla Kitoye Ajasa, to si ni aburo ọkùnrin kan ṣoṣo.
Awọn obi Oyinkansola, Ọlọla Kitoye ati Lucretia Olayinka Moore, ni tọkọtaya akọkọ ni Naijiria ti ilẹ Gẹẹsi yoo kọkọ fi oye 'Knight' da lọla.
Laarin ọdun 1903 si 1909 ni Oyinkan pari ẹkọ rẹ nile ẹkọ girama Anglican Girls, ko to morile ilu ọba lati tẹsiwaju.
Oyinkan dara pọ mọ ẹgbẹ Girls Guildes nigba to wa nilu oyinbo, oun si ni obinrin akọkọ ọmọ Naijiria ti yoo jẹ Alakoso ẹgbẹ naa.
Oyinkan pada sile lati ilu ọba lọdun 1920 lẹyin to kawe tan nile ẹkọ orin nilẹ Gẹẹsi, to si n ṣíṣẹ olukọ nile ẹkọ girama Anglican Girls, to ti kẹkọọ jade.
Nigba to pada dele, Oyinkan dara pọ mọ ẹgbẹ Girls Guides nilu Eko, to si n ṣiṣẹ kara lori eto ẹkọ ọmọbinrin, oun si tun ni obinrin akọkọ ti yoo wa ọkọ ayọkẹlẹ nilu Eko.
Bakan naa ni akọni obinrin yii tun jẹ ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo jẹ alakoso fun ẹgbẹ Girls Guides lọdun 1931.
Igbeyawo ati ọsan aye Oyinkan Abayomi
Yoruba maa n ni ilẹ obìnrin kii pẹ su, igba ara si la n bura, Oyinkan ṣe igbeyawo pẹlu agbẹjọro kan, Morohunfolu Abayomi lọjọ Kẹwaa, osu Karun un, ọdun 1923.
Amọ o ṣe ni laanu pe, kokoro iku ko jẹ ki awọn tọkọtaya tuntun naa gbadun ara wọn, nitori osu meji lẹyin igbeyawo ni Morohunfolu jade laye.
Akọsilẹ sọ fun wa pe iwaju ile ẹjọ ti Morohunfolu ti lọ gba ẹjọ ro, ni wọn ti yin ìbọn fun, ti Oyinkan si di opo ọsan gangan.
Oyinkan pinnu pe oun ko ni fẹ ọkọ miran mọ nitori iku ọkọ rẹ aarọ ba a lojiji, to si dun wọnu egungun.
Lẹyin ọdun meje ti Morohunfolu dara ilẹ, Oyinkan tun ba ifẹ pade, to si di aya Dokita kan, Kofoworola, ti wọn ni orúkọ baba tiẹ naa jẹ orúkọ baba ọkọ aarọ Oyinkan, eyiun Abayomi.
Oyinkan Abayomi ko nilo lati paarọ orúkọ mọ nitori orúkọ ọkọ aarọ rẹ, naa ni orúkọ ọkọ rẹ keji.
Amọ itan miran sọ pe, Kofoworola John ni orúkọ ọkọ kejì to fẹ Oyinkan.
A gbọ pe Oyinkan lo pọn ni dandan fun Dokita naa pe ti yoo ba fẹ oun, o gbọdọ paarọ orukọ rẹ si Abayomi, tii ṣe orúkọ ọkọ rẹ aarọ.
Nitori ifẹ nla to ni si Oyinkan, a ka a pe Kofoworola naa ṣe bẹẹ, idi ti eyi fi ri bẹẹ, ko si ẹni to ye.
Iṣẹ takuntakun ti Oyinkan Abayomi ṣe fun agbega obinrin ati iran ọmọniyan
Oyinkan jẹ agbẹnusọ fun ifẹsẹmulẹ ẹtọ awọn obinrin nigba aye rẹ ati eto ẹkọ wọn, to si tun n ja fun ibaradọgba ati ipo kan naa fun takọtabo.
O ṣe agbekalẹ ẹgbẹ kan to wa fun awọn obinrin to kawe, eyiun British West Africa Educated Girls Club, amọ orukọ ẹgbẹ naa ti parada si Ladies Progressive Club.
Ẹgbẹ ọhun si ni Oyinkan lo lati kan sawọn eekanlu lawujọ fun ikowojọ, eyi to fi da ile ẹkọ girama Queen's College silẹ lọdun 1927 nilu Eko.
Ile ẹkọ girama yii ni akọkọ ladugbo Yaba nigba naa, to si ni ilegbe fun takọtabo akẹkọọ, Oyinkan si ni ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo ṣiṣẹ olukọ nibẹ.
Akọni obìnrin yii tun ko awọn Iyalọja jọ sinu oniruuru ẹlẹgbẹjẹgbẹ, to si tun da ẹgbẹ Young Women Christian Association, YMCA silẹ.
Oyinkansola Abayomi ko tun gbẹyin ninu oselu, to si n rọ awọn araalu lati maa kopa ninu eto iselu labẹle, ki wọn si jija gbara fun ominira Naijiria.
Ni ọjọ Kẹwaa, osu karun un, ọdun 1944, ni Oyinkan tun da ẹgbẹ oselu akọkọ to wa fun obinrin nikan silẹ ti orukọ rẹ n jẹ Nigerian Women Party, NWP pẹlu obinrin mejila mii.
Ọdun 1954 ni ọbabinrin ilẹ Gẹ̀ẹ́sì fi oye ọlọla, Sir and Lady, da Oyinkan ati ọkọ rẹ, Kofoworola Abayomi lọla.
Oyinkan tun ṣiṣẹ bii Kanselọ to n soju awọn obinrin ni ijọba ibilẹ Eko fun odindi ọdun meje gbako, to si lọ soju fun ẹtọ awọn obinrin nile asofin lẹkun Iwọ oorun Naijiria.
Ko tan sibẹ, Oyinkan tun jẹ aarẹ ẹgbẹ apapọ fawọn obinrin, National Council Of Women Societies ati aarẹ ayeraye fun ẹgbẹ Girls Guides lọdun 1982.
Awọn oye ati ami ẹyẹ ti wọn fi da Oyinkan Abayomi lọla
Oyinkansola Abayomi ni awujọ mọ riri rẹ, ti wọn si fi oniruuru oye ati ami ẹyẹ da lọla.
Lara awọn oye ti Oyinkan jẹ nigba aye rẹ ni Moroye tilu Eko ati iya Abiye tilẹ Ẹ̀gbá.
Ijọba apapọ tun fi oye Order of the Federal Republic of Nigeria, OFR da Oyinkan lọla,
Nigba ti ijọba Gẹẹsì tun fi oye Member of the order of the British Empire MBE da lọla.
Lakotan, ijọba Eko fi opopona kan ladugbo Ikoyi sọri Oyinkan Abayomi lati fi bu ọla fun akọni obinrin naa, eyi to gbajumọ nilu Eko
Iku Oyinkan Abayomi ati ẹkọ ti igbe aye rẹ kọ wa
Ọjọ Kọkandinlogun, osu Kẹta, ọdun 1990 ni akọni obinrin, ololufẹ mẹkuunu ati asaaju obinrin naa, Ọlọla Oyinkansola Abayomi jade laye lẹni ọdun mẹtalelaadọrun.
Ṣugbọn bi onirese onirese Oyinkan ko ba fingba mọ, eyi to ti fin silẹ ko le parun.
Igbe aye akínkanjú obìnrin yii si lo n kọ wa pe obìnrin kii ṣe ohun elo alailagbara, ti ko wulo.
Itan aye obìnrin yii tun n kọ wa lati jẹ akínkanjú, olufẹ mẹkuunu ati ajafetọọ ọmọniyan ni ipokipo ti a ba wa, boya a jẹ ọkùnrin abi obìnrin.
A wa n gbadura pe ki ọba oke tẹ ọlọla Oyinkansola Ajasa aya Abayomi si afẹfẹ rere.
Comments