Ọkọ olùrànlọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta dèrò àhámọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekúpa ìyàwó rẹ̀


 Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti sọ pe Pasitọ Favour to jẹ ọkọ Shimite Winifred Bello oluranlọwọ gomina ipinlẹ Delta to doloogbe ti wa lọdọ awọn ọlọpaa fun aabo ẹmi rẹ, lẹyin tawọn ẹbi iyawo rẹ fẹsun kan an wi pe oun lo ṣeku pa iyawo rẹ.


Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, SP Bright Edafe, to ba BBC Pidgin sọrọ ṣalaye pe gbọyii sọyii ori ayelujara lasan ni ọrọ tawọn kan n gbe kiri pe ọkọ Shimite lo pa a nigba ti wọn n ja.


SP Edafe ni ọkọ oloogbe funra rẹ lo pe ọlọpaa lọjọ Aje wi pe iyawo oun ṣe aisan ki o to ku, amọ, awọn ẹbi rẹ n dunkoko lati ṣe ikọlu si oun.Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ayẹwo yoo waye lori oku Shimite lati mọ ohun to ṣokunfa iku arabinrin naa, ṣugbọn SP Edafe ni oju ti awọn ọlọpaa fi wo ọrọ naa bayii ni pe ọlọjọ lo de fun Shimite.


O fikun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni akọsilẹ iṣẹlẹ kankan pe ede-ai-yede waye laarin ọkọ Shimite ati ẹni kankan lẹyin iku iyawo rẹ.


SP Edafe ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn ẹbi Shimite n dunkoko lati ṣe ikọlu si Ọgbẹni Favour lori iku iyawo rẹ.


Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe lẹyin ti ọkọ Shimite pe ọlọpaa wi pe awọn ẹbi iyawo oun n dunkoko moun lawọn ọlọpaa mu un sọdọ fun abo ẹmi rẹ.


Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta sọ pe awọn yoo ṣe iwadii ohun to ṣe okunfa iku Shimite, lẹyin ti ẹbi rẹ ti kan si ọlọpaa lori iṣẹlẹ naa.


Ileeṣẹ ọlọpaa Delta sọrọ lẹyin tawọn eeyan kan ti n sọ lori itakun ayelujara wi pe Shimite ku lẹyin ti ọkọ rẹ huwa ipa si i.


Tameta Sunday to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Shimite fẹsun kan Ọgbẹni Favour pe oun lo ṣeku pa iyawo rẹ.


Tameta ni ''o nira fun mi lati gba pe ọga mi Shimite White Eagle ti dagbere faye.


O dun mi pe ẹni ti wọn n pe ni pasitọ lo fopin si gbogbo erongba wa lori awọn nnkan ti a fẹ jọ ṣe papọ.


Nibo ni a ti fẹ bẹrẹ bayii, ni ṣe lo n ṣe mi bi ẹni wi pe o si wa laye,'' Tameta lo sọ bẹẹ.


Harrison Gwamnishu, to jẹ oludamọran gomina ipinlẹ Delta lori ọrọ ilu atawọn ọdọ naa kẹdun akẹgbẹ rẹ to doloogbe.


O ni ''ile aye yii. O ti su mi lati maa gbọ iroyin ibanujẹ. Sun re o arẹwa Shimite White Eagle.''


Ta a ni Shimite Winifred to di oloogbe?


Shimite ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi alakoso ajọ UNIDO ni ipinlẹ Delta.


Shimite jẹ ọkan lara awọn eeyan to pe fun imuṣẹ eto iranwọ ijọba apapọ fawọn ti ko rọwọ họri ni ipinlẹ Delta.


O ṣe agbatẹru eto kan ti o pe orukọ rẹ ni ''African Pot'' lori ẹrọ amohunmaworan eyi to fi ṣe igbelarugẹ aṣa ilẹ Afirika ati irinajo igbafẹ l'Afirika.


Shimite tun jẹ ọkan lara ọmo igbimọ ajọ USAID ati ajọ NEXTT to n ri si ọrọ okowo ati igbokegbodo ọkọ ni Naijiria.


Bakan naa ni o tun jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ alaṣẹ ajọ FESECA to n ri si ayipada ọrọ aje awọn orilẹede ilẹ Afirika.


Shimite tun jẹ akoroyin lori irinajo igbafẹ pẹlu iwe iroyin Daily Trust ati Leadership nigba aye rẹ.