Mọ̀ nípa ọdún eégún ìlú Ekan-Meje, níbi tó ti jẹ́ èèwọ̀ láti gbé àjẹkù oúnjẹ́ lọ sílé látibi ọdún
Ọkan pataki lara ọdun to gbajumọ to si gbilẹ nilẹ Yoruba ni ọdun Egungun jẹ.
Ko fẹẹ si ilu kankan nilẹ Yoruba, nibi ti wọn kii tii ṣe ọdun Egungun amọ ti onikaluku ni asiko ati igba ti eegun wọn maa n jade.
Ni ilu Ekan Meje to wa ni ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, ọdun eegun ko gbẹyin nibẹ amọ bayii la n ṣe nilẹ wa, o le jẹ eewọ ni ilẹ ibomiran.
Lodi si bi egungun ṣe maa n jade ni ọdọọdun ni ọpọ ibi nilẹ Yoruba, ẹẹkan laaarin ọdun mẹta ni eegun maa n jade ni ilu yii.
Gbogbo ijade awọn eegun yii kii si ju ọsẹ meji lọ ti wọn tun fi maa wọle pada, to si tun di ẹyin ọdun mẹta ki wọn to tun le jade.
Ni ọjọ ti ọdun yii ba kọkọ bẹrẹ lawọn eegun kọọkan yoo maa jade lati maa dara loriṣiriṣi, ti wọn yoo si maa pidan lọkan-o-jọkan.
Ọjọ meje gbako ni eyi yoo fi waye, tawọn idile kọọkan yoo maa gbe eegun wọn jade ti wọn yoo si lọ maa pidan ni aafin ọba ilu naa.
Nigba to n sọrọ nipa ọdun naa, ọkan lara awọn ọmọ igbimọ alamojuto, Kayode Bamidele Ojopagogo sọ pe, ọjọ kọọkan ni awọn eegun yoo fi maa ṣere ni aafin kabiyesi ilu naa pẹlu alaye pe bi ilẹ ba ti su lawọn eegun naa yoo maa dan oogun wo lara wọn lati mọ bi ẹnikọọkan ṣe lagbara si.
Elekan ti ilu Ekan Meje, Ọba Ọlaniyan David Adekunle sọ pe ,ayeye ọdun Egungun naa jẹ eyi to ṣe akojọpọ gbogbo eegun ilu ọhun.
Ọba Adekunle ṣalaye pe ti ọdun naa ba ti ku ọla ni wọn maa kọkọ lọ si igbo oro lati wure ki ọdun naa le lọ lai si wahala kankan.
O fi kun alaye rẹ pe lasiko ayẹyẹ yii ni awọn eeyan tun maa n ṣe iranti iya wọn to ti doloogbe nipa gbigbe ounjẹ lọ si ile ti wọn ti bi iya wọn lati fi han pe awọn ko gbagbe iya naa.
Yatọ si eyi, lati igba ti ọdun ba ti bẹrẹ ni wọn ti maa n gbe ounjẹ lọ si kaa awọn eegun lati agboole kọọkan, awọn ọkunrin ti wọn jẹ ọmọ agboole naa yoo lọ maa jẹun ni kaa awọn eegun naa amọ tawọn obinrin ko gbodọ debẹ.
Eewọ kan to wa nibẹ ni pe ẹnikẹni ko ni anfaani lati mu ajẹku ounjẹ lọ sile rẹ.
Gbogbo awọn ọmọ ilu Ekan Meje nile ati loke okun lo maa n peju pesẹ lati kopa nibi ayẹyẹ ọdun naa paapaa lati woran bawọn eegun naa ṣe maa n fi oogun dara.
Lẹyin ti awọn eegun keekeeke ba pari ere wọn tan ni ọjọ meje akọkọ ni Eegun Ẹlẹwẹ, to jẹ agba eegun ilu naa yoo ṣẹṣẹ wa jade fun ọjọ meje.
Ijade eegun Ẹlẹwẹ fun ọjọ meje ni wọn fi maa kadii eto naa nilẹ titi di ọdun mẹta miiran ti ayẹyẹ naa tun maa waye.
